Ní abúlé kan lórí Òkè Kenya ní Ìlà-oòrùn Afrika, ọmọ kékeré kan ṣiṣẹ́ nínú oko pẹ̀lú
màmá rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Wangari.
在东非肯尼亚山的山腰上,有一座小村庄,村庄里有一个小女孩和妈妈一起在田里劳作,这个女孩叫旺加里。
Wangari fẹ́ràn láti wà ní ìta. Ní ọgbà ilé oúnjẹ ẹbí rẹ̀, ó tu ilẹ̀ pẹ̀lú àdá rẹ̀. Ó fi
àwọn èso kékeré sínú ilẹ̀.
旺加里很喜欢呆在户外。在她家的农田里,旺加里用弯刀劈开土地,把小种子播撒到温暖的泥土里。
Àkókò tí ó fẹ́ràn ni ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí alẹ́ bá ti lẹ́ jù, Wangari mọ̀ pé àkókò ti tó láti lọlé.
Ó máa gba ọ̀nà tínínrín inú oko tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò tí ó bá tí ń padà lọlé.
Wangari jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kò lè dúró títí tí ó máa fi lọ sí ilé-ìwé. Ṣùgbọ́n màmá àti
bàbá rẹ̀ fẹ́ jẹ́kí ó dúró sílé láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọ̀dún méje, ẹ̀gbọ́n
rẹ̀ ọkùnrin sọ fún àwọn òbí wọn kí wọ́n jẹ́ kí ó lọ sí ilé-ìwé.
Ó fẹ́ràn láti kàwé!
Wangari kọ́ oríṣiríṣi nǹkan nínú ìwé tí ó kà.
Ó ṣe dáradára ní ilé-ìwé débi pé wọ́n pè wá sí ìlú Amerika láti kàwé.
Inú Wangari dùn gán an ni! Ó fẹ́ mọ̀ si nípa gbogbo ayé.
Ní Yunifásítì kan ní ìlú Amerika, Wangari kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tuntun. Ó kọ́ nípa bí
àwọn ewé ṣe ń dàgbà. Ó rántí bí òun ṣe dàgbà: bí òun ṣe ń ṣeré pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀
lábẹ́ àwọn igi inú igbó Kenya.
Bí ó ṣe ń kàwé si ni ó ń ri bí òun ṣe fẹ́ràn àwọn ènìyàn Kenya. Ó fẹ́ jẹ́ kí wọ́n ní
ayọ̀ àtí òmìnira. Bí ó ṣe ń kàwé si ni ó ń rántí ilé rẹ̀ ní Afrika.
Nígbá tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà sí Kenya.
Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè rẹ̀ ti yípadà. Àwọn oko ńlá ti pọ̀si nílẹ̀.
Àwọn obìnrin kò ní igi láti fi dáná.
Àwọn ènìyàn tòṣì. Ebi sì ń pa àwọn ọmọdé.
Wangari mọ nǹkan tí óun lè ṣe. Ó kọ́ àwọn obìnrin láti gbin igi pẹ̀lú èso.
Àwọn obìnrin náà ta àwọn igi náà,wọ́n sì lo owó tí wọ́n rí láti fi tọ́jú ẹbí wọn.
Inú àwọn obìnrin náà dùn púpọ̀. Wangari ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè borí wàhálà wọn.
Lẹ́hìn àkókò púpọ̀, àwọn igi tuntun náà dàgbà sí igbó, àwọn odò náà sì padà.
Gbogbo ènìyàn ní Afrika ni ó gbọ́ nǹkan tí Wangari ṣe.
Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn igi ni ó ti dàgbà nípasẹ èso ti Wangari.
Wangari tí ṣiṣẹ́ gan an. Gbogbo
ènìyàn káàkiri àgbáyé ni ó mọ̀,
wọ́n sì fun ní ẹ̀bùn ńlá kan. Wọ́n
ń pè é ní ẹ̀bùn ti Nobel Peace,
òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́
gbà á.
旺加里努力工作,引起了全世界的注意,人们授予她诺贝尔和平奖,她是非洲第一位获得这份殊荣的女性。
Wangari kú ní ọ̀dún 2011, ṣùgbọ́n a lè ronú nípa rẹ̀ nígbàkígbà tí a bá rí igi arẹwà
kan.